Monday, 3 November 2014

ISUBU AWON IRANSE OLORUN 2 Sam 1:27



ISUBU AWON IRANSE OLORUN 2 Sam 1:27.
Bi a ba n soro nipa isubu awon iranse- Olorun, a n so nipa isubu awon alagbara ati akoni igbagbo lati inu ogo sinu ofo. O tumo si wipe ki eni to ti figba kan gbona- janjan ninu ife Olorun wa pehinda, ko palana-da, ki o si kehin si Olorun.

Nigba ti iranse- Olorun ba ya kuro ni oju ona tooro, ti o si bo si oju ona gbooro; nigba ti iranse Olorun ba jade kuro ninu ife Olorun to si tipa se bee gba ofa nipa tara tabi nipa ti emi, iru eni bee ti subu.  

AWON ASIRI PATAKI TI A GBODO MO NIPA ISUBU IRANSE-OLORUN

1. Opolopo awon akoni ati alagbara igbagbo to subu loni lo ti figba kan gbona giri- giri fun Olorun, won ti se opo ise iyanu, won si ti jere oke aimoye okan si ijoba- orun- Ise Aposteli 1:15-20.

2. Opolopo won lo bere dara- dara pelu Kristi, won n lepa iwa mimo, won si ni ipinnu lati pari ere ije won daradara sugbon takute esu mu won, won si subu-

3. Opolopo awon akoni wonyi ni ko fura wipe satani atawon omo ogun orun apaadi n kora jo po, won si n lepa isubu won lonakona pelu ibinu ati irunu nla- 1 Peter 5:8-9.

4. Ota kan soso naa to gbe awon yen subu lo n lepa lati fa awa naa lule, o si n foju sona lati saseyori lori wa gege bi o se se lori awon wonyen.

Idi niyen ti Bibeli fi kilo fun wa pe eni to baro wipe oun duro ki o kiyesara- 1 Kor 10:12.

5. Ko si akoni tabi alagbara kan ti ko lee subu ayafi enikeni to ba gboran si ilana Bibeli to n kiyesara, to si n figba gbogbo wa oju Olorun ati ore ofe Re ninu adura adagba ikoko ati iranlowo adura awon eniyan Olorun- 2 Tess 3:1-2.
6. Awon to subu ko rokan wipe awon lee subu beyen naa, o ti sele tan ki oju opolopo to wale- Matt 26:69-75.

7. Satani ko so ireti nu lori enikeni lai bikita bi o ti wu ki iru eni bee ti pe to, jinle to tabi lagbara to ninu igbagbo, niwon igba ti onitoun ba si n gbe inu ago- ara.

8. Isubu iranse Olorun kii se ohun ti a fi n sesin eleya tabi takuroso laarin ara wa pelu enu egan, ibanuje nla ni fun orun ati ajalu buburu fun ijo Kristi- 2 Sam 1:17-27.

9. Awon ojulowo omo Olorun to ni oye eko Bibeli ko ni kede isubu iranse Olorun tabi fi won se eleya bikose pe ki won fi iwariri ati okan irele ran won lowo lonakona lati tete mu won bo sipo- Gal 6:1-3.

10. A gbodo fara bale keko, ki a si kogbon lara apeere awon to subu ki awa naa ma baa se iru asise ti won se- 1 Kor 10:6-12.

11. Olorun mo bi o se maa n fi owo anu ati ore ofe gbe awon iranse Re to ba subu dide- Psalmu 37:23-24, Psalmu 34: 18-19.

12. Ni opolopo igba, eni to subu ti ronupiwada, o si ti tun ona re se niwaju Olorun atawon to se asise si (restitution) sugbon awon alaimokan a si maa fi oju elese wo iru iranse Olorun bee.


OKUNFA ISUBU AWON IRANSE OLORUN- 1 Kor 10:6-12.

1. Fifi ife isaaju sile- Ifihan 2:1-5.

v     Ife isaaju ni igbona okan ati itara wa fun Olorun ati Oro iwa mimo Re lasiko ti a koko ni iriri ati idaniloju igbala eyi to mu ki a maa fi gbogbo ipa ati okan wa lepa lati mo ati lati maa se ohun ti yio mu inu Olorun dun nigba naa.
v     Fifi ife isaaju sile tumo si gbigba emi irewesi ati iyemeji laaye lati ba igbagbo wa ninu awon ileri Olorun ati Oro Re je-

Boya nitori…
-          Ogun isoro tabi iponju olojo pipe- Onidajo 6:11-13.
-          Ireti pipe-
-          Oro egan tabi ifiniseleya lati enu awon alaigbagbo.
-          Ise rere awon eniyan buburu nigba ti awon olododo n jiya- Mal 3:14-15, Psalmu 73:2-14.
-          Oro odi ati imisi irewesi nipase awon eleko eke- Gal 5:7-9.
Sakiyesi Gal 3:1-4.
                               
v     Fifi ife isaaju sile tumo si fifi ise pupo “nihin ati lohun” dira eni lowo (ai ri aaye lati sabojuto okan tiwa) - 1 Oba 20:35-43.  O tumo si sise aniyan ati laala nitori ohun pupo lai fi aaye sile fun ilepa lati mo ati lati se ife Olorun- Lk 10:38-42.

Ami awon nkan wonyi saba maa n fara han nigba ti…
-          Nigba ti diduro niwaju awon eniyan lati maa se ise iranse ba ti n di lemolemo to bee ti a ko fi ri aaye lati kunle niwaju Olorun fun ibasepo mimo pelu Re mo.
-          Nigba ti adura ita gba-n- gba laarin opo ero ba ti n di gbogbo igba de bi wipe ko si aaye fun wa lati wa oju Olorun ninu adura adagba nikoko mo.
-          Nigba ti bibojuto awon ara ita ko ba fun wa laaye lati bojuto idile wa mo.
-          Nigba ti ttitoju awon miran ko ba fi aaye gba wa lati toju ago ara wa mo.
-          Nigba ti a ba ti n gba awe olojo gbooro lai wa akoko fun sisasaro ninu oro Olorun ati adura adagba.
-          Fifi gbogbo agbara wa se ise iranse fun awon eniyan nigba gbogbo lai si eni kankan to n se ise iranse fun okan ti wa (Seminars, Bible studies, Refresher course, conference, etc).
-          Fifi ife isaaju sile tumo si riri ara eni gege bi eni to ti kun oju osuwon igbagbo, eni ti o ti gbon tan ti ko nilo abojuto adari tabi se isiro fun enikeni-
-          Kikun fun emi igberaga ati ijora eni loju nitori ifarahan awon ebun emi- Hosea 13:1.
-          Idaniloju ati igbekele ninu ara eni (self confidence), sisogo ati si sinmi le awon aseyori ati ibukun ise iranse asiko yi- Fil 3:12-14.
-          Kikegan ati fifi oju alaimoose wo awon akegbe tabi asiwaju ti ko ni ebun tabi ise- iranse nla bii tiwa.
-          Siso awon oro iponra- eni- le ati isera- eni-logo niwaju awon eniyan gege bi eni nla pataki kan- Ise Aposteli 12:21-24.
-          Lilepa fun awon oruko ati oye- nla pelu ipo- ola lawujo. Won a wipe opon ti sun, level ti change – Matt. 23:5-12
-          Sise afojudi si oro-Olorun, kikegan ikilo tabi ibawi awon adari rere, ati kikorira awon to n bani so otito – Gal 4:15-16

2. Fifi ipa eran-ara se ise ti emi tabi fi fi ohun ija ti ara jagun emi – Gal 3:3

Nigba ti a ba ti fi ife wa isaaju sile, ti a ko si ni ibasepo timotimo pelu Olorun mo, iwonyi ni awon ami ti yio bere si nii fara han:
-          Fifi ete ati ogbon-ori dipo itoni Emi-Mimo.
-          Fifi owo ati awon eniyan nla-nla ti a mo ri dipo ifihan agbara Emi-Mimo.
-          Lilepa fun isowo ati karakata to lee mu owo wole dipo ise ijere-okan ati itankale ihinrere.
-          Siso oro ihale, egun ati ikoni-laya-je lati fi awon omo-ijo sinu ipaya lati ribi jega-bale won lori dipo fifara bale ko won ni eko oro Olorun, bibawon wi ninu ife ati fifi okan won le Olorun lowo ninu adura ikoko.
-          Si sare tele awon olowo, olola atawon eni nla aye lati wa iranlowo won lori isoro tabi ipenija ti o dojuko wa dipo wiwa oju Olorun fun ona-abayo.
-          Sisoro nipa eto oselu atawon oro to n lo lawujo lori pepe dipo wiwaasu ogidi oro Olorun.
-          Wiwa ori ero ayelujara fun akori ati koko inu iwaasu dipo wiwa inu Bibeli.
-          Sise awokose ati afarawe awon woli ati iranse-Olorun nla (big man of God) dipo Kristi Jesu – Heb. 12.2.

3. Emi Aikiyesara – Matt. 7:3-5
Ai kiyesara lo maa n mu ki a bojuto ogba-ajara elomiran nigba ti ogba ajara ti wa n baje lo. Orin  Sol. 1:6.

* Alaafia ati ileera ninu ago-ara wa – Fil 2:25-30

Ago-ara ni oko ti Emi-Mimo n lo lati fi sise. Bi ago-ara naa ba si ti baje nitori ai ri itoju, Emi Mimo a fo jade, ise-iranse a si pari. Bi ise-iranse ba si ti pari, awon t o n tele wa a sa pada, won a tun wa elomiran lo.

* Eto igbeyawo ati idile wa – 1 Timo. 3:8.

- Iyawo wa ni ojuse akoko ti a gbodo koko bojuto saaju enikeni ninu ise-iranse. A gbodo sa gbogbo ipa wa lati koo ati lati muu dagba ninu emi, ki o lee wa pelu wa nigba gbogbo gege bi:-
1. Alabakegbepo
2. Alabaro ati olubanidamoran
3. Alajogbadurapo
4. Ore kori-kosun

Bi a ba ti kuro lori iyawo wa, ogiri idile a lanu, ala-n-gba ota a si wole lati wa furugbin buburu tabi lati wa ja wa lole ogo.

Eleyi si lo maa n fa oniruuru isele buburu fun iranse-Olorun:
1. Ai se deede okan pelu iyawo je anfani kan pataki ti satani maa n lo lati ta ofa agbere sinu aye iranse-Olorun ati lati faaye gba awon ajeji-obinrin.
2. Ai si ni isokan pelu iyawo maa n fi aaye sile fun ofa-okunkun (emi aisan, iku tabi emi isiwahu) lati ba iranse-Olorun, iyawo tabi awon omo won.
3. Ai ni ifowosowopo ati inu kan pelu iyawo wa maa n yori si ogun adaja eyi to tete maa n fa isubu fun iranse- Olorun

* Ibasepo pelu awon obinrin- 1 Tess 5:22, 2 Kor 4:1-2.
- Fifaramo ati sise wole- wode pelu obinrin ti kii se iyawo wa lona to lee mu ifura si dani.
- Sise ibarinpo tabi ajosepo pelu obinrin miran lona ti o lee mu ki iyawo wa ma lee gberi wa je.
- Di danikan se igbani- nimoran tabi adura itusile fun obinrin ni koro tabi nibi okunkun.
- Sise iranlowo pataki fun tabi gbigba nkan lowo obinrin laije ki iyawo wa mo sii.

* Fifi asiri aileera tabi asise wa pamo fun awon to lee ran wa lowo- Psalmu 38:17-19.

Iyawo/ oko ati adari wa ninu ise- iranse je awon ti a ko gbodo ti owo to n dun wa boso fun- Jms 5:16.   

2 comments:

Anonymous said...

Thank you for your words

Anonymous said...

Thanks for your words may God bless you