
Oto ni ipe, oto si ni ebun-Emi. Awon
ebun-emi ni irin-ise ti a fi fun awon eni ipe lati lee se ise- iranse won lona
ti yoo laseyori – 1 Kor 12:7. Ko si kristaini kan
tabi iranse-Olorun kan
ti ko ni ebun – Emi tire, eyi ti a fi fun lati oke wa – 1 Kor 12:11.
Lotito, Olorun lo n fun awon eni –ipe ni
oniruuru ebun- emi, sugbon ojuse onikaluku ni lati sawari ati lati samulo awon
ebun naa lekunrere – 1 Tim 4:14-16, 2 Tim 1:6. Bi eniyan ba ni ipe- Olorun
nitooto, sugbon bi ko ba mo bi a ti n sawari ebun- emi ati bi a ti n samulo
won, onitoun a maa jiya ninu ise-iranse bi eni ti ko ni ipe ni- Psalm 49:20.
KINI
AWON EBUN- EMI?
Awon ebun-emi ni akanse ipe tabi agbara ti
a yonda fun kristaini tabi iranse- Olorun kookan latoke wa lati se awon akanse
ise- isin tabi ise- iranse fun iranlowo awon elomiran, igbero ijo Olorun,
titankale ihinrere ati lati mu ogo ba oruko Olorun nibi gbogbo.
IDI
TI A SE GBODO SAWARI AWON EBUN- EMI KI A SI
SAMULO WON
1. Ki a ma baa je ope nipa awon ohun tie mi
– 1 Kor 12:11.
2. Ki a lee mu ete ati erongba Olorun fun
iwasaye wa se-
3. Ki a lee je ohun- elo si ola nigba ti
ise-iranse wa ba mu ere nla wa fun Olorun-
4. Ki a lee mu ife Olorun se ninu aye, ki imole ogo Re lee
kun gbogbo aye bi omi ti n kun inu okun-
5. Ki a lee gba awon eniyan kuro ninu
agbara satani si Olorun, ki won ki o lee di eda- titun ninu Kristi-
IPELE
META TI A PIN AWON EBUN EMI SI- 1 Kor 12:4-7.
AWON
EBUN EMI – Awon
wonyi ni awon ebun meseesan ti a daruko ninu iwe 1 Kor 12:8-10. Ipele meta ni a
pin awon ebun meseesan wonyi si gege bi a ti salaye won nisale yi:
1. AWON EBUN IMISI
- Isotele-
- Oniruuru- ede-
- Itumo- ede-
2. AWON
EBUN AGBARA
- Igbagbo-
- Ebun Imularada-
- Ise Iyanu ise-
3. AWON EBUN IFIHAN
- Oro Ogbon
- Oro Imo
- Imo Emi-yato.
ΓΌ
Awon ebun meseesan wonyi ni a n
pe ni awon ebun- emi nitori pe lati owo Emi Mimo ni a ti n yonda won fun wa – 1
Kor 12:4, 8-11. Awon ebun wonyi si wa fun gbogbo kristiani ti o ba ti gba Emi
Mimo lati fi jere fun Kristi – 1 Kor 12:7, 11.
AWON
EBUN ISE- IRANSE
Iwonyi ni awon ebun maraarun ti a daruko
ninu iwe Efesu 4:11. A n pe awon ebun wonyi pe o je ebun- ipe ti Jesu Oluwa fi
pe iru awon kristiani kan
ti o si ya won soto fun akanse ise- iranse ninu ijo- Efesu 4: 11-14. Idi niyen
ti a tun se maa n pee ni awon ebun ise- iranse marun (5- fold ministry).
se gbogbo kristiani ni a yonda fun lati ni
awon ebun marun wonyi, bee si ni kii se ohun ti eniyan lee fun ara re.
Oruko awon ebun ise- iranse maraarun naa
niwonyi:
1. AWON
APOSTELI
Awon wonyi ni akanse iko ati iriju ti
Olorun pe, ti o yan ti o si ran jade fun akanse ise- iranse ti o nii se pelu
fifi ipile otito ihinrere lele ni awon agbegbe titun tabi sisi awon eniyan loju
si otito ipile ihinrere ti a ko mo tabi ti a ko ka si tele – 1 Kor 3:9-11.
Iwonyi ni apeere awon Aposteli ninu Bibeli:
v
Awon Aposteli mejila- Lk
6:13-16.
v
Matthias- Acts 1:24-26.
v
Paulu- Gal 1:1
v
Barnaba- Acts 14:14.
v
Androniku ati Junia – Rom 16:7.
2. AWON
WOLI
Awon wonyi ni akanse iranse ti Olorun gbe
dide pelu agbara ati akanse ifami- ororo- yan lati je agbenuso fun Oun niwaju
awon eniyan-
Ise- iranse woli ju siso asotele nipa isele
ojo iwaju nikan lo, o nii se pelu siso okan- Olorun fun awon eniyan, kikilo fun
awon apehinda ati kikede iwa- mimo Olorun ati idajo atoke wa lori awon eniyan
buburu ti ko ronupiwada-
Iwonyi ni apeere die ninu awon woli ninu
Bibeli:
¨
Elijah-
¨
Elisha
¨
Mika
¨
Jeremiah
¨
Awon woli lati Jerusalem- Acts
11:27-28.
¨
Agabu- Acts 21:10-11.
¨
Juda ati Sila- Acts 15:32.
3. AWON
EFANGELISTI
Awon wonyi ni awon iranse ti Olorun moomo
gbe dide pelu akanse agbara ati ifami- ororo- yan lati kede ihinrere opolopo
okan sinu ogba- ajara Kristi-
4. AWON
OLUSO AGUNTAN
Awon wonyi ni awon iko ti Olorun yan pelu
akanse ifami- ororo- yan ati agbara lati bojuto awon aguntan- Olorun ati lati
maa mu won dagba sii ninu ore-ofe ati imo Jesu Kristi-
5. AWON
OLUKONI
Awon wonyi ni Olorun fi akanse ifami- ororo
yan ti o si fun ni ogbon ati imo- ijinle nipa awon ohun ti emi lati fi oro
Olorun koni ni ona to lee yeni yeke yeke – Acts 18:25, 2 Tim 1:11.
AWON EBUN ISE- ISIN (Motivational gifts)
Niwon
igba ti a ti ri aridaju lati inu eko oro Olorun wipe ko si kristiani kan ti
Olorun ko fun ni ebun kan tabi omiran, O wa ku sowo onikaluku lati sawari awon
ebun naa ati lati Awon wonyi ni ebun meje ti a daruko ninu iwe Rom 12:3-8. A n
pe won ni ebun ise- isin nitori pe o je awon ebun ti Olorun gbin sinu kristiani
kookan lati ru won soke fun oniruuru ise- isin ninu ara Kristi (ijo Olorun).
Awon ebun wonyi je ifarahan Olorun lati ba aini ijo pade, lati gbe ijo ro ati
lati maa mu ijo dagba sii. Ko si kristiani kan
ti Olorun ko fi ebun kan
tabi ju be e lo fun.
Oruko
awon ebun mejeeje naa niwonyi:
ISOTELE: Awon ti a fi ebun yi fun ni
Olorun saba maa n lo gege bi “oju” lati ri asiri ibi ti esu tabi ese fara pamo
si ninu ijo, lati toka sii ati lati so okan Olorun jade fun awon eniyan re nipa
isele atehinwa, isele isinsinyi tabi ti ojo iwaju.
Olorun
maa n lo ebun isotele lati mu ese awon ayanfe duro ninu ijo, lati gbawon
niyanju ati lati tu won ninu ni – 1 Kor 14:3.
ISE-
IRANSE
Awon
kristiani to ni ebun ise- iranse (iranlowo) ni Olorun saba maa n lo lati se
akanse iranlowo tabi ise- iranse fun awon ayanfe fun idagbasoke ijo Olorun – Lk
22:24-27. Awon to ni ebun yi lee se ise- isin won ninu ijo Olorun nipase orin-
ihinrere, ere ori itage (drama), asona (usher) olutoju ayika ati sise ise- isin
fun awon bii opo, alaini, omo orukan ninu ijo abbl.
OLUKONI- Awon wonyi ni Olorun fun ni imo
ati ogbon lati maa wadi ijinle otito eko oro Olorun ati lati maa fi ko awon ijo
fun ifese mule won ninu Kristi.
Iru won
lee je oluko ile- eko ojo isinmi, oluko eko Bibeli (Bible study teachers),
oluko ile iwe Bibeli, oluko awon ewe abbl.
IGBANINIYANJU- Awon wonyi ni kristiani ti
Olorun fun ni ebun igbaninimoran (counselling) lati maa to awon ayanfe sona ati
lati maa mu won lokan le lasiko iponju.
IFIFUNNI- Awon wonyi ni kristiani to ni
ebun ififunni lati maa fi owo atawon ohun ini won se iranlowo ati atilehin fun
ijo Olorun, awon iranse Olorun ati awon ara ninu Oluwa.
OLORI- Awon kristiani wonyi ni a fun ni
ore- ofe lati lee se akoso ijo (church administration) tabi awon elegbejegbe
ninu ijo (olori egbe obinrin rere, okunrin rere, abbl).
AANU- Awon wonyi ni Olorun saba maa n
lo ninu ijo lati sakiyesi awon to ni isoro, iponju tabi aini kan ati lati se
agbateru bi isoro naa yoo se di yiyanju.
Won saba
maa n se aanu ati iranlowo fun awon alaini, awon opo, alaisan abbl ninu ijo
Olorun.
AKIYESI
PATAKI
A gbodo
sakiyesi wipe gbogbo awon ebun wonyi lo n sise papo ni ifowosowopo gege bi
oniruuru eya ninu ara kan soso lai si iyapa tabi adase- 1 Kor 12:12-31.
BI O SE
LEE SAWARI ATI BI O SE LEE SAMULO AWON EBUN EMI RE
samulo
won lekun rere.
Iwonyi ni
awon igbese ti a lee gbe:
1. Ya ara
re si mimo fun Olorun, ki o si fi ara re jin fun sise ife Re- 2 Tim 2:19-21.
2. Mura
lati fi tokan tokan sin labe adari ati lati sise takuntakun fun ilosiwaju,
ise-rere ati anfani awon elomiran lai wa ere tabi iyin eniyan- Deut 34:9, 2 Oba
3:11, 2 Tim 1:6.
3. Maa
kiyesi ara re-
- Kini
awon nkan ti o je ipongbe okan re, ohun to maa n wu o lati se tabi ohun ti o n
ni irusoke lati dawole?
- Kini
idi ti awon nkan naa se n wu o lati maa se? Bi o ba je nitori ife- owo, ilepa
fun ipo, okiki, ominira lati te ife eran ara lorun, iyin eniyan tabi iru awon
nkan miran ti o yato si mimu ogo ba oruko Kristi ati idagbasoke fun ijo Olorun;
sora etan esu ni – Acts 8:17-23.
- Nje
awon nkan naa ro e lorun lati maa se ati wipe se o n mu eso jade?
- Kini ijerisi
awon eniyan (awon adari ati ara ninu Oluwa) nipa awon nkan naa nigba ti o ba n
se won?
4. Bere
si nii fi otito inu lo awon ebun re nibi ti o wa, ki o ma si se kegan ibere
kekere – Lk 16:10, Matt 25:21.
5. Maa fi
emi irele ati okan- tutu gba itoni, ikoni ati ibawi awon adari lori lilo awon
ebun re – Gal 2:1-2.
6. Mase
kegan tabi se ilara eni to ti n samulo ebun tire lona to tayo ju tire lo.
Sugbon re ara re sile ki o si fara bale kekolara won pelu inu rere- Heb 6:12,
13:7. (iwe, Cd etc)
7. Maa
jowu ohun rere, ki o si maa lepa lati tele apeere awon to ti ni idagbasoke ju o
lo.
Sugbon ma
se sojukokoro si ebun elomiran tabi kegan ebun re- Rom 11:13.
8. Mase
so ara re di orogun tabi ba enikeni se ifigagbaga aito nipa lilo awon ebun re.
Sugbon maa se ohun gbogbo fun ijere okan, igbero awon ara ninu Oluwa ati
idagbasoke ijo Kristi pelu inu kan ati okan mimo- 1 Peter 4:10.
9. Sora
fun emi oroju, imele, tabi iwa ole to maa n mu ki eniyan sun ojuse oni si ola-
Oniwasu 11:4-6, Rom 12:11.
10. Sora
fun emi iberu ati iyemeji. Maa lo awon ebun re lore koore pelu emi igboya ati
igbagbo- 2 Tim.1:6-8. Bi o ba se n lo ebun re si ni yio maa po si ti yio si maa
dagba sii. Nitori naa, maa fi gbogbo igba ati akoko re lo awon ebun naa.
11. Mase
gba ki esu ya ebun re lo lati se lodi si eto Olorun, ife Olorun tabi oro Olorun
ninu aye enikeni tabi ninu ijo Olorun- James 3:13-18.
12. Sora
fun lilo ebun-emi pelu okan arekereke lati mu ifekufe ti ara re se- 2 Sam
15:1-13.
14 comments:
Oluwa yio so agbara dotun
E seun Olorun a bunkun yin.
Oro iyanju nla ni eyi. More anointing.
May God continue renew your strength.
Olorun yio tubo maa fun yin ni imo ati oye sii,nitori pe mo ri ogbon ko ninu Oro iyanju yii
Ise iranse yin yio maa tesiwaju li oruko jesu
Opolo yin oni daru loruko Jesu
Ez sir
Ejo sir bawo no mosele tumo fun alore sir eranmilowo lakaye him koni daru sir
Olorun a turbo maa fi imo kun imo, Oye kun Oye ATI ogbon kun ogbon fun yin loruko Jesu Kristi Oluwa wa Amin.
We bless God
Kin ni anpe ni Alore? AWON wo ni Alore? Kin ni idi ti afi pe won ni Alore?bawo lasele da alore mo?
E se pupo, Olorun a so agbara yin di otun. More Anointing to function well
Ninu iwe wo ati ese wo lo wa ninu bibeli
Post a Comment